Bismillahir Rahmanir Rahim.
Ni ojo Kirendilogbon osu
kefa Odun 1999
eyi to se deede Osu keta
Odun 1419
Ni oruko olorun oba ajoke
aiye, Oba asake orun.
Eyin fun Olorun, oba aso
I ke, ola ati alafia olorun ko
maa ba Asaaju wa,
Anabi Muhammad, ati awon ara
ile re ati awon Sahabe re
Pourquoi ai-je renoncé au Mouvement Ahmadiyya ?
Why did I Renounce Ahmadiyyah ?
IGBIMO AWON ADAJO ISLAM NI AGBAIYE
Kilode ti mo fi kuro ninu Ijo Ahmadiyya ?
Alagba Asaaju Ijo Ahmadiyya
“Eto ni ki njewo niwaju olorun ati awon eniyan wipe bi mo se nte Siwaju ninu iwadi igbagbo awon Ahmadiyya ti mo si ngbiyanju lati fi awon itoka won fi han ; mo rii wipe Ijo Ahmadiyya ntu awon eniyan agbaye Je, won si nfi laakaye awon ope, alaïmokan ti won Je omo Ijo won fi sere” Oro yi wa Lati enu Dr Balogun.
Ninu awon iwe iroyin ti won fan ka silu Nigeria ni Odun 1974, Dr Ismaïl
A.B. Balogun, okan ninu awon Asaaju Ijo Ahmadiyya Ja iro awon awijare Ijo
Ahmadiyya, o si Jewo niwaju gbogbo agbaye wipe Ijo ti won bi owun Sinu re, ti
won si to owun ninu re, Ahmadiyya ntan awon eniyan Je.
Oluko (professor) imo Esin Islam ati imo ede Larubawa ni ile eko giga
(Univesity) ti ilu Ibadan, ni Orile ede Nigeria, Ojogbon Dr Balogun gbe igbesi
aiye re fun itesiwaju Ijo Ahmadiyya, Won si to-o won ko-o lo ni awon ijinle eko
Ijo Ahmadiyya lati lee di ojulowo agboroso abi asoju won-Fun gbogbo awon odun
ti o lo ninu Ijo Ahmadiyya, awon waasu re to jeti ni gbese to dun-un gbo, to si
kun fun kiki etan ati ekun rere alaye, fa pupo odo sinu Ijo Ahmadiyya. Beeni,
yiyose kuro ninu Ijo re je sababi mimi titi ati awon rogbodiyan ati awon
ariyanjiyan ti o je ki pupo ninu awon omowe, ojogbon, onilaakaye ri imole ati
otito esin Islam, ti won si kuro ninu Ijo Ahmadiyya.
Igba ironupiwada ti olohun ma ngba oun ni ti
awon ti nwon fi alaïmo sise buburu,
lehin na ti nwon ronupiwada laïpe. Awon wonyi
ni awon ti olohun yio gba ironupiwada won. Olohun si je
Olumo, Ologbon. (Alukur’an
AN-NISAI-ori kerin, ese ketadilogun)
Lehinna Dr Balogun se alaye sababi iyose re kuro ninu Ijo Ahmadiyya, o si
pe awon ipade, awon alaye to se fun awon alatako re ninu awon ipade yen, o ko
won sinu iwe kan ti akole re nje : „Islam ati Ahmadiyya ni Orile ede Nigeria“.
Ninu iwe yi Dr Balogun nse alaye bi owun ati awon agba omowe gegebi owun se fi
aïmokan wonu Ijo Ahmadiyya atipe esin ti awon ba lodo awon baba awon ni atipe
awon iranse Ahmadiyya ti ilu Pakistan nwon pa funfun ninu iro fun awon eniyan,
atipe awon ijosin won farajo ti esin Islam ni apakan to si wipe igbagbo won
yato si igbagbo Musulumi ododo.
Ninu iwe yi Dr Balogun nse alaye igbagbo oju dudu ti oni si awon iranse Ijo
Ahmadiyya ti ilu Pakistan.
Sibe-sibe, awon iwadi to peye to si kun imo ijinle ni oju ona eko Ijo Ahmadiyya ti Dr Balogun se, tan imole abamo fun-un nitoripe awon atako adapa iro ti o ri ninu oro won ko fun-un ni abayori kan yato si wibe ko tu asiri Ijo Ahmadiyya fun gbogbo agbaye. Ipinu re si dara.
Pelu wipe Dr Balogun Je araba nla ninu Ijo Ahmadiyya o si tun Je ojulowo onimo ijinle ni oju ona sein Islam, Dr Balogun gbagbe ara ere sinu aïmokan, oju dudu aïridi otito ninu Ijo Ahmadiyya lati igba ewe re titi o fi ni ju ogoji odun lo.
Nipa awon itoka iro ti awon iranse Ahmadiyya nwon fayo ninu Alukur’an ati oro Anabi Muhammed ati awon akosile awon oluberu olohun lati le fi Jeri adapa iro won, Dr Balogun nso bayi :
« Ero mi (ti mo fi nse iwadi ofintoto awon itoka ti awon Ahmadiyya nfi se eri) ni otito, ni wipe ki emi na le dara mi loju lati le gbogun ti awon alatako Ijo Ahmadiyya. Gegeti olumo ile eko giga (University) okan mi bale wipe ikede mi loju ona Ahmadiyya gbodo fese rinle pelu awon eri to daju to wa lati inu orisun sein Islam (Alukur’an ati Hadiths).
Ni ipari awon iwadi ofintoto awon itoka to awon iranse Ahmadiyya nwon fi nse eri, mo mulèmofo.
Eto ni ki njewo niwaju olorun ati awon eniyan wipe bi mo se nte siwaju iwadi igbagbo Ijo Ahmadiyya ti mo si ngbiyanju lati fi awon itoka won fi han, mo ri-i wipe Ijo Ahmadiyya ntu awon eniyan agbaye Je, won si nfi Laakaye awon ope, alaïmokan ti won Je omo Ijo won fi sere.
Opolopo igba ni won ma nka awon akowe ti ero won farajo ero Ahmadiyya gbangba,sugbon won a ma fi ete ati ogbon èwè fi yi oro won pada ero won farajo ero Ijo Ahmadiyya.
Ayafi igbati olukawe ati oluwadi ba la awon itoka, eri ti awon Ahmadiyya nwon fi se awijare lori akole oro ti awon akowe yi se atako awon Ahmadiyya le lori, ki imole otito to tan si olukawe ati olumadi yi, ona ti awon iranse Ahmadiyya ti ilu Pakistan ngba tan awon eniyan agbaye je (Ibid. p. 86-87).
Ijinle iwadi ofintoto ti Dr Balogun se ninu awon atata iwe (ojulowo iwe) to je ti esin Islam tanna imole to gbamuse fun-un wipe awon oludasile ati awon oludari Ijo Ahmadiyya won mo-mo fi ogbon ewe fi si awon alaïmokan lona.
Awon ipinnu ti Dr Balogun ko sinu iwe re niyi : « o f’oju han gbangba ninu awon oro ti a nbaabo wa wipe Ijo Ahmadiyya ko ri nkankan mu ninu oro awon akowe yi, ti won je alatako won koja awon apakan oro awon akowe yi to fee dabi wipe ofarajo awon ero oju dudu won leyi to je wipe iwadi ofintoto alaye oro yi fi han gbangba wipe ero ngba awon akowe yi tako ero ngba Ijo Ahmadiyya, eyi ni Sababi ti awon Ahmadiyya nwon fi nfi obgon ewe fi yi oro awon akowe yi pada wipe ero won ba ero Ahmadiyya mu.
Ni agbo awon omowe, olaju, won a maa pe iru iwa jamba bayi ni iyi ero akowe pada.
Iru iwa Jamba bayi lodi si ofin ti gbogbo agbaye fi lole fun eto awon akowe. Niti paapa ko see gba mora, ko si dun-un gbo, ko ba laakaye mu wipe ki a ma yi ero ngba akowe pada si ero ngba tiwa Iwa ikorira ni, egbin si tun ni
Ni apejuwe ki a wo Alukur’an ori 2 ese 59 ati ori 7 ese 162 ti nso bayi wipe : « Sugbon awon ti nwon se abosi yi oro na pada yato si eyi ti a so fun won, nitorina, a so ajakalè-arun kalè lati sanma le awon to se abosi lori, nitoripe won je odese »
« Awon alabosi ninu won si yi oro na pada yato si eyiti a ba won so, nitorina a si ran iya si won lati Sanma nitoripe won se abosi » eyi je arikogbon fun awon Ahmadiyya. (Ibid. p. 94-95.
Awon ti nda adapa iro mo olohun nikan ni awon ti ko ni ibbagbo si awon
ami olohun atipe awon elewonni ni opuro. (Alukur’an ori 16 ese 105).
Lehin iyose re kuro ninu Ijo Ahmadiyya ti o han si gbogbo eniyan, Dr
Balogun di eniti awon iranse Ahmadiyya ti ilu Pakistan ntori re Jarawon niyan.
Gegebi apejuwe olori Ijo Ahmadiyya nilu Nigeria ni asiko yen, ogbeni Molvi
Ajmal Shahid, fun esi kan to kuru gidi ninu eyi to se alaye ikedun omo iya re
ro ku (Ibid. P. 97)“, Oludari Ijo Ahmadiyya ni West-Africa, ogbeni Moulvi
Naseen Saili tenumo wipe Dr Balogun kuro ninu Ijo Amadiyya nitori esin Islam.
(Ibid. P. 99) ; pelu bee, sibe-sibe awon iranse Ahmadiyya miran nwon nbere
sababi ijade re kuro ninu Ijo Ahmadiyya.
Gegebi alaye, Dr Balogun enito ti mo awon ona ti Ijo Ahmadiyya ngba ba
oruko awon to ba kuro ninu Ijo won je lati odun gboro, so bayi :
„Nigba ewe mi, won ko mi soju ona wipe ki nmaabowo fun awon iranse
Ahmadiyya ti ilu India ati Pakistan ti won ndari ijosin wa. Nigbati iranse de
fun awon asaaju wa, lati odo awon asaaju wa de odo tiwa, awa gba gbogbo ohun ti
won so fun wa nitori igbagbo ati ifokantan oju dudu ti ani siwon. Awon waasu
won jo ohun to dara, oro won ba laakaye mu loju wa, a si gba awon awijare won
tokan-tokan. Won a ma toka si awon iwe ofin esin Islam lati fi jeri eke won, lati
fi se eri ifarahan bi otito won. Awa si gba awon itoka won gbo lalaï se iwadi
ofintoto won nitori igbagbo ti awa ni siwon.
Ilana won ati ero won ni iyawa ya awon Musulumi adodo, awon eniti Ijo
Ahmadiyya npegan won, tiwon nsayonu-so siwon wipe won ko se esin Islam bo se to
ati bo ti se ye.
Awon iranse Ahmadiyya nse bi eni ti o fe fi ododo esin Islam fi han wa ni
oruko Ijo Ahmadiyya.
Opolopo igba ni nwon ma nso funwa wipe awon atako ti ndoju ko Ijo Ahmadiyya ni ilu India siwaju ipinya, lehinna nilu Pakistan Je ifesemule eri ododo Ijo Ahmadiyya. Pataki Julo, pelu irorun koni nwon fi ngba ojise kan gbo ni ilu ti a bi. I si abi ni Orile ede re. Awijare yi na jo otito loju wa, a si gba won gbo tokan-tokan.
(« Islam pelu Ahmadiyya ni Orile ede Nigeria » p. 85-86)
Ni odun meedogbon sehin Dr Balogun ri aridaju ona ati ogbon ti awon ojulowo iranse Ahmadiyya ngba ti won nfi si won alaïmokan lona.
Iwa Jamba ti awon iranse Ahmadiyya nhu ko da le lori aïko fi igbagbo won ati itan won fi han awon omo Ijo won, sugbon won tun nyi awon esin Islam pada beeni won nyi laakaye awon omo Musulumi pada, won si ngbiyanju lati pin esin Islam si ijo ati egbe keekeke laarin awon musulumi ti won je alaïmokan pelu asotenumo ati asodun won.
Dr Balogun
so bayi :
„Pelu wipe Ijo Ahmadiyya ti wa ni Orilede Nigeria yi lati nkan bi aadota
odun, o dami loju wipe pupo ninu awon omo Ijo Ahmadiyya ati awon iranse re tun
wa ninu okunkun alaye igbagbo Ahmadiyya ati aniyan won. Gegebi apejuwe, laïpe
yi nigbatii atako to gbona bere si doju ko Ijo Ahmadiyya ni orile ede Nigeria
yi, ni apakan ninu awon asaaju Ijo Ahmadiyya bere si-i akoko igba wipe Ghulam
Ahmad nperare ni Ojise olorun“
(„Islam pelu Ahmadiyya ni Orilede Nigeria » p. 3)
O foju han gbangba wipe awon Ahmadiyya ngbe ododo igbagbo won pamo fun opolopo ninu awon omo Ijo won. Nitoribe nigbati okan ninu awon odo mode kurin musulumi ti won je omowe ni orilede Nigeria. Al-Hadj L. B. Ahusto ki olorun bawa ke to pe Ijo Ahmadiyya ti ilu okeere wa si orilede Nigeria , Nigbati odomode kurin omowe yi lo si ilu Britain lati le tesiwaju ninu eko re, nibe ni o ti pade awon iran India ti won je Ahmadiyya ti nwon ngbe ilu Britain. Nigbati o ko eko ipele alakoko o pada wa si orilede re lati wa yo awon omo egbe re kuro ninu Ijo Ahmadiyya » (Ibid. p. 2)
Ni
otito, lati ibere pepe won, igbimo Ijo Ahmadiyya nlo awon ilana awon iranse Ijo
Christina lati fi da ote Sile laarin awon alaïmokan ati awon musulumi ododo,
eyi ni ona ti awon omo Ijo won na nfi po si-i.
Akase, won mo daju wipe botilewu kori awon omo-omo awon eni ti awon Ijo Ahmadiyya lo ogbon ewe, ogbon arekenda fun ti won fi ko won sinu Ijo Ahmadiyya ntu awon je ni, die ninu won ni yio le pada kuro ninu Ijo na.
Dajudaju nwon ba awon baba won ninu isina
Awon na nsure tele ona won. Dajudaju opolopo awon eni akoko ti sina siwaju won (Alukur’an, As-saaffat ori 37 : ese 69-71)
Dr Balogun nsalaye bayi wipe, no odun 1974, nigbati Ijoba ilu Pakistan ati agbajo orilede ti Islam ni agbaye kede wipe Ijo Ahmadiyya Je Ijo igbogun ti Islam, Dr Balogun bere si-i gbeja Ijo ti won bi-i sinu re, O si nfi otito Ijo Ahmadiyya fi han.
“Ninu iwe yi, O dara wipe ki nsalaye akojo awon ona ti Ijo Ahmadiyya ngba lo ogbon arekenda fun awon eniyan lati fi ko won sinu Ijo won. (Gebebi apejuwe : ilosi awon Ijo Ahmadiyya ti ilu Pakistan) labenu lalaïkose ikede kankan rara, sugbon oye ati iriri fi han mi wipe sise bee yo farajo itu ona asiri ati ibanije fun igba gboro, yo si dabi wipe won yo mi kuro ninu Ijo won ni mo fi se bee. Atipe awon omo Ijo kankan koni teti gbo oro mi. Mo ti salaye ohun ti mo ri Olohun ni eleri mi, pataki Julo nitori ohun ti eri okan nso fun mi nipa awon omo musulumi Orilede Nigeria ti won je elegbe mi ni esa, ati gbogbo agbaye Islam ni apapo.
Emi ko ni ero ngba atako Ijo Ahmadiyya, mo semi ninu Ijo na fun igba gbooro
ti mo fi ni ife re lokan.
Sugbon pelu bee iyapa enu kankan ko waye ri laarin Ijo Ahmadiyya pelu esin Islam. O soroyan fun mi wipe ki nkede fun anfasi esin Islam lai-fi-bo po-bo’yo wipe Ijo Ahmadiyya ntu awon eniyan agbaye je” (Ibid. P. 17)
A ro wipe latara imole awon aridaju ti Dr Balogun, awon ti won darapo mo
Ijo Ahmadiyya won yio pada kuro ninu Ijo na bo sinu esin Islam.
Awon eniti iyanu Alukur’an ati eko Anabi wa Muhammad sele si ni igbesi aiye
won, ati awon eniti awon eniyan npuru fun, ki olorun tan imole sigbesi aiye
gbegbo wa, ki a le sin olorun bo se to ati bo se ye.
Dajudaju awon alaigbagbo ti nwon seri (awon eniyan) kuro loju ona ti
olohun ti nwon si ni ojise (olohun) lara lehin ti ito sona ti han fun won, nwon
ko le se inira kan fun
olohun, atipe yio so ise won di asan.
(Alukur’an, Muhammad Ori 47 : ese 32)
Dr Syed Rashid Ali
P.O. Box 11560
Dibba Al Fujairah United Arab Emirates